-
Jẹ́nẹ́sísì 41:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Ó pa dà lọ sùn, ó sì lá àlá míì. Ṣírí ọkà méje tó yọmọ dáadáa, tó sì dára+ jáde láti ara pòròpórò kan. 6 Lẹ́yìn náà, ṣírí ọkà méje tó tín-ín-rín, tí atẹ́gùn ìlà oòrùn sì ti jó gbẹ hù jáde. 7 Àwọn ṣírí ọkà tó tín-ín-rín náà wá ń gbé ṣírí ọkà méje tó yọmọ dáadáa, tó sì dára mì. Ni Fáráò bá jí, ó sì rí i pé àlá ni òun lá.
-