35 Ó tún lóyún lẹ́ẹ̀kan sí i, ó bí ọmọkùnrin kan, ó sì sọ pé: “Lọ́tẹ̀ yìí, màá yin Jèhófà.” Torí náà, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Júdà.*+ Lẹ́yìn ìyẹn, kò bímọ mọ́.
5 Àmọ́ ọ̀kan lára àwọn àgbààgbà náà sọ fún mi pé: “Má sunkún mọ́. Wò ó! Kìnnìún ẹ̀yà Júdà,+ gbòǹgbò+ Dáfídì,+ ti ṣẹ́gun+ kó lè ṣí àkájọ ìwé náà àti èdìdì méje rẹ̀.”