-
Jẹ́nẹ́sísì 30:35, 36Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
35 Ní ọjọ́ yẹn, ó ya àwọn òbúkọ abilà àtàwọn tó ní oríṣiríṣi àwọ̀ sọ́tọ̀ àti gbogbo abo ewúrẹ́ aláwọ̀ tó-tò-tó àtàwọn tó ní oríṣiríṣi àwọ̀. Ó ya gbogbo èyí tó ní funfun lára àtàwọn tí àwọ̀ wọn pọ́n rẹ́súrẹ́sú sọ́tọ̀ láàárín àwọn ọmọ àgbò, ó sì ní kí àwọn ọmọ rẹ̀ máa bójú tó wọn. 36 Lẹ́yìn ìyẹn, ó fi àyè tó fẹ̀ tó ìrìn àjò ọjọ́ mẹ́ta sí àárín òun àti Jékọ́bù, Jékọ́bù sì ń bójú tó èyí tó ṣẹ́ kù nínú agbo ẹran Lábánì.
-