19 Kí o mú méjì-méjì lára gbogbo oríṣiríṣi ohun alààyè+ wọnú áàkì náà, kí ẹ lè jọ wà láàyè. Kí o mú wọn ní akọ àti abo;+ 20 àwọn ẹ̀dá tó ń fò ní irú tiwọn, àwọn ẹran ọ̀sìn ní irú tiwọn àti gbogbo ẹran tó ń rákò lórí ilẹ̀ ní irú tiwọn, méjì-méjì ni kí o mú wọn wọlé sọ́dọ̀ rẹ kí wọ́n lè wà láàyè.+