20 àwọn tó ṣàìgbọràn nígbà tí Ọlọ́run ń fi sùúrù dúró* ní àwọn ọjọ́ Nóà,+ lákòókò tí wọ́n ń kan ọkọ̀ áàkì,+ tí a fi gba àwọn èèyàn díẹ̀ là nígbà ìkún omi, ìyẹn ọkàn* mẹ́jọ.+
5 Kò sì fawọ́ sẹ́yìn láti fìyà jẹ ayé ìgbàanì,+ àmọ́ ó dá ẹ̀mí Nóà, oníwàásù òdodo sí+ pẹ̀lú àwọn méje míì + nígbà tó mú ìkún omi wá sórí ayé àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.+