ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Léfítíkù 3:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 “‘Ó jẹ́ àṣẹ tó máa wà fún àwọn ìran yín títí lọ, ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé: Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀+ èyíkéyìí.’”

  • Léfítíkù 7:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 “‘Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ èyíkéyìí+ ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé, ì báà jẹ́ ti ẹyẹ tàbí ti ẹranko.

  • Léfítíkù 17:10
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 10 “‘Tí ọkùnrin kankan ní ilé Ísírẹ́lì tàbí tí àjèjì kankan tó ń gbé láàárín yín bá jẹ ẹ̀jẹ̀+ èyíkéyìí, ó dájú pé mi ò ní fi ojú rere wo ẹni* tó ń jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi yóò sì pa á, kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.

  • Léfítíkù 17:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 “‘Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan tàbí àjèjì kan tó ń gbé láàárín yín bá ń ṣọdẹ, tó sì mú ẹran ìgbẹ́ tàbí ẹyẹ tí ẹ lè jẹ, ó gbọ́dọ̀ da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde,+ kó sì fi erùpẹ̀ bò ó.

  • Diutarónómì 12:16
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 16 Àmọ́, ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ rẹ̀;+ ṣe ni kí ẹ dà á sórí ilẹ̀ bí omi.+

  • Diutarónómì 12:23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 23 Ṣáà ti pinnu pé o ò ní jẹ ẹ̀jẹ̀,+ má sì yẹ ìpinnu rẹ, torí pé ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí,*+ o ò sì gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀mí* pọ̀ mọ́ ẹran.

  • Ìṣe 15:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 àmọ́ kí a kọ̀wé sí wọn láti ta kété sí àwọn ohun tí àwọn òrìṣà ti sọ di ẹlẹ́gbin,+ sí ìṣekúṣe,*+ sí ohun tí wọ́n fún lọ́rùn pa* àti sí ẹ̀jẹ̀.+

  • Ìṣe 15:29
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 29 láti máa ta kété sí àwọn ohun tí wọ́n fi rúbọ sí òrìṣà,+ láti máa ta kété sí ẹ̀jẹ̀,+ sí ohun tí wọ́n fún lọ́rùn pa*+ àti sí ìṣekúṣe.*+ Tí ẹ bá ń yẹra fún àwọn nǹkan yìí délẹ̀délẹ̀, ẹ ó láásìkí. Kí ara yín ó le o!”*

  • Ìṣe 21:25
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 25 Ní ti àwọn onígbàgbọ́ tó wá látinú àwọn orílẹ̀-èdè, a ti kọ ìpinnu wa ránṣẹ́ sí wọn pé kí wọ́n yẹra fún ohun tí wọ́n fi rúbọ sí àwọn òrìṣà,+ kí wọ́n yẹra fún ẹ̀jẹ̀,+ fún ohun tí wọ́n fún lọ́rùn pa*+ àti ìṣekúṣe.”*+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́