9 Ó di ọdẹ alágbára tó ń ta ko Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń sọ pé: “Bíi Nímírọ́dù ọdẹ alágbára tó ta ko Jèhófà.” 10 Ibi tí ìjọba rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ni* Bábélì,+ Érékì,+ Ákádì àti Kálínè, ní ilẹ̀ Ṣínárì.+
2 Nígbà tó yá, Jèhófà fi Jèhóákímù ọba Júdà lé e lọ́wọ́,+ pẹ̀lú àwọn ohun èlò kan ní ilé* Ọlọ́run tòótọ́, ó sì kó wọn wá sí ilẹ̀ Ṣínárì*+ sí ilé* ọlọ́run rẹ̀. Ó kó àwọn ohun èlò náà sínú ilé ìṣúra ọlọ́run rẹ̀.+