3 ó sì sọ fún un pé: ‘Jáde kúrò ní ilẹ̀ rẹ àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ, kí o sì wá sí ilẹ̀ tí màá fi hàn ọ́.’+ 4 Lẹ́yìn náà, ó jáde kúrò ní ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, ó sì ń gbé ní Háránì. Lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ kú,+ Ọlọ́run darí rẹ̀ láti ibẹ̀ pé kí ó lọ máa gbé ní ilẹ̀ tí ẹ̀ ń gbé báyìí.+