25 Ẹ̀yin ni ọmọ àwọn wòlíì àti ti májẹ̀mú tí Ọlọ́run bá àwọn baba ńlá yín dá,+ tí ó sọ fún Ábúráhámù pé: ‘Gbogbo ìdílé tó wà láyé yóò rí ìbùkún nípasẹ̀ ọmọ* rẹ.’+
8 Bí ìwé mímọ́ ṣe rí i ṣáájú pé Ọlọ́run máa pe àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè ní olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, ó kéde ìhìn rere náà fún Ábúráhámù ṣáájú pé: “Ipasẹ̀ rẹ ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fi rí ìbùkún gbà.”+