-
Jẹ́nẹ́sísì 19:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Wọ́n ń pe Lọ́ọ̀tì, wọ́n sì ń sọ fún un pé: “Àwọn ọkùnrin tó wá sọ́dọ̀ rẹ ní alẹ́ yìí dà? Mú wọn jáde ká lè bá wọn lò pọ̀.”+
-
-
2 Pétérù 2:6-8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ó mú kí ìlú Sódómù àti Gòmórà jóná di eérú, ó tipa bẹ́ẹ̀ dá wọn lẹ́bi,+ ìyẹn sì jẹ́ àpẹẹrẹ àwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.+ 7 Ó gba Lọ́ọ̀tì olódodo là,+ ẹni tó banú jẹ́ gidigidi nítorí ìwà àìnítìjú* àwọn arúfin èèyàn— 8 torí ojoojúmọ́ ni ọkùnrin olódodo yẹn ń mú kí ọkàn* rẹ̀ gbọgbẹ́ nítorí ohun tó rí àti ohun tó gbọ́ tí àwọn arúfin yẹn ń ṣe nígbà tó ń gbé láàárín wọn.
-