7 Nítorí Melikisédékì yìí, ọba Sálẹ́mù, àlùfáà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, pàdé Ábúráhámù nígbà tó ń pa dà bọ̀ látibi tó ti pa àwọn ọba, ó sì súre fún un,+ 2 Ábúráhámù wá fún un ní ìdá mẹ́wàá gbogbo nǹkan. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìtúmọ̀ orúkọ rẹ̀ ni “Ọba Òdodo,” bákan náà, ọba Sálẹ́mù, ìyẹn “Ọba Àlàáfíà.”