Sáàmù 27:1 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 27 Jèhófà ni ìmọ́lẹ̀ mi+ àti ìgbàlà mi. Ta ni èmi yóò bẹ̀rù?+ Jèhófà ni odi ààbò ayé mi.+ Ta ni èmi yóò fòyà? Àìsáyà 41:10 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 10 Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ.+ Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ.+ Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́,+Ní tòótọ́, màá fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin.’ Róòmù 8:31 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 31 Kí ni ká wá sọ sọ́rọ̀ yìí? Tí Ọlọ́run bá wà lẹ́yìn wa, ta ló lè dènà wa?+ Hébérù 13:6 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 6 Ká lè nígboyà gidigidi, ká sì sọ pé: “Jèhófà* ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?”+
27 Jèhófà ni ìmọ́lẹ̀ mi+ àti ìgbàlà mi. Ta ni èmi yóò bẹ̀rù?+ Jèhófà ni odi ààbò ayé mi.+ Ta ni èmi yóò fòyà?
10 Má bẹ̀rù, torí mo wà pẹ̀lú rẹ.+ Má ṣàníyàn, torí èmi ni Ọlọ́run rẹ.+ Màá fún ọ lókun, àní, màá ràn ọ́ lọ́wọ́,+Ní tòótọ́, màá fi ọwọ́ ọ̀tún òdodo mi dì ọ́ mú ṣinṣin.’
6 Ká lè nígboyà gidigidi, ká sì sọ pé: “Jèhófà* ni olùrànlọ́wọ́ mi; mi ò ní bẹ̀rù. Kí ni èèyàn lè fi mí ṣe?”+