-
Jẹ́nẹ́sísì 17:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Ní ti ohun tó o sọ nípa Íṣímáẹ́lì, mo ti gbọ́. Wò ó! Èmi yóò bù kún un, màá mú kó bímọ, màá sì mú kí ó di púpọ̀ gan-an. Ó máa bí ìjòyè méjìlá (12), màá sì mú kí ó di orílẹ̀-èdè ńlá.+
-
-
Jẹ́nẹ́sísì 25:13-16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
13 Orúkọ àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì nìyí, orúkọ wọn gẹ́gẹ́ bí ìdílé tí wọ́n ti wá: Àkọ́bí Íṣímáẹ́lì ni Nébáótì,+ lẹ́yìn náà ó bí Kídárì,+ Ádíbéélì, Míbúsámù,+ 14 Míṣímà, Dúmà, Máásà, 15 Hádádì, Témà, Jétúrì, Náfíṣì àti Kédémà. 16 Àwọn yìí ni ọmọ Íṣímáẹ́lì, orúkọ wọn sì nìyí, gẹ́gẹ́ bí ibi tí wọ́n ń gbé àti ibùdó* wọn, wọ́n jẹ́ ìjòyè méjìlá (12) ní àwọn agbo ilé+ wọn.
-