19 Ọlọ́run fèsì pé: “Ó dájú pé Sérà ìyàwó rẹ máa bí ọmọkùnrin kan fún ọ, kí o sì sọ ọ́ ní Ísákì.*+ Màá sì fìdí májẹ̀mú mi tí mo bá a dá múlẹ̀, ó máa jẹ́ májẹ̀mú ayérayé fún àtọmọdọ́mọ* rẹ̀.+
3 “‘Nígbà tó yá, mo mú Ábúráhámù + baba ńlá yín láti òdìkejì Odò,* mo mú kó rin gbogbo ilẹ̀ Kénáánì já, mo sì sọ àwọn ọmọ* rẹ̀ di púpọ̀.+ Mo fún un ní Ísákì;+