-
Hébérù 11:17-19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Nígbà tí a dán Ábúráhámù wò,+ ká kúkú sọ pé ó ti fi Ísákì rúbọ tán torí ìgbàgbọ́—ọkùnrin tó gba àwọn ìlérí náà tayọ̀tayọ̀ fẹ́ fi ọmọkùnrin kan ṣoṣo tó bí rúbọ+— 18 bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ti sọ fún un pé: “Látọ̀dọ̀ Ísákì+ ni ọmọ* rẹ yóò ti wá.” 19 Àmọ́, ó ronú pé Ọlọ́run lè gbé e dìde tó bá tiẹ̀ kú, ó sì rí i gbà láti ibẹ̀ lọ́nà àpèjúwe.+
-