-
Jẹ́nẹ́sísì 24:22, 23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Nígbà tí àwọn ràkúnmí náà mumi tán, ọkùnrin náà mú òrùka wúrà tí wọ́n ń fi sí imú, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ìlàjì ṣékélì* àti ẹ̀gbà ọwọ́ méjì tí wọ́n fi wúrà ṣe, tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣékélì* mẹ́wàá, ó sì fún obìnrin náà, 23 ó wá bi í pé: “Jọ̀ọ́ sọ fún mi, ọmọ ta ni ọ́? Ṣé yàrá kankan wà ní ilé bàbá rẹ tí a lè sùn mọ́jú?”
-