11 Áńgẹ́lì Jèhófà fi kún un pé: “O ti lóyún, wàá sì bí ọmọkùnrin kan, kí o pe orúkọ rẹ̀ ní Íṣímáẹ́lì, torí Jèhófà ti gbọ́ nípa ìyà tó ń jẹ ọ́. 12 Ó máa dà bíi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú igbó. Ó máa bá gbogbo èèyàn jà, gbogbo èèyàn á sì bá a jà, òdìkejì gbogbo àwọn arákùnrin rẹ̀ ni á máa gbé.”