3 Àmọ́ ẹ̀rù ń bà mí pé lọ́nà kan ṣáá, bí ejò ṣe fi ẹ̀tàn fa ojú Éfà mọ́ra,+ a lè sọ ìrònú yín dìbàjẹ́, tí ẹ ó sì yà kúrò nínú òtítọ́ inú àti ìwà mímọ́* tó yẹ Kristi.+
14 Àmọ́ àdánwò máa ń dé bá kálukú nígbà tí ìfẹ́ ọkàn rẹ̀ bá fà á mọ́ra, tó sì tàn án jẹ.*+15 Tí ìfẹ́ ọkàn náà bá ti gbilẹ̀,* ó máa bí ẹ̀ṣẹ̀; tí ẹ̀ṣẹ̀ náà bá sì ti wáyé, ó máa yọrí sí ikú.+