-
Jẹ́nẹ́sísì 12:11-13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Bó ṣe fẹ́ wọ Íjíbítì, ó sọ fún Sáráì ìyàwó rẹ̀ pé: “Jọ̀ọ́, gbọ́ ohun tí mo fẹ́ sọ! Mo mọ̀ pé o rẹwà gan-an lóbìnrin.+ 12 Tí àwọn ará Íjíbítì bá sì rí ọ, ó dájú pé wọ́n á sọ pé, ‘Ìyàwó rẹ̀ nìyí.’ Wọ́n á pa mí, àmọ́ wọ́n á dá ọ sí. 13 Jọ̀ọ́, sọ fún wọn pé àbúrò mi ni ọ́, kí nǹkan kan má bàa ṣe mí torí rẹ, kí wọ́n lè dá ẹ̀mí mi sí.”*+
-