-
1 Jòhánù 3:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Ohun tí a máa fi dá àwọn ọmọ Ọlọ́run àti àwọn ọmọ Èṣù mọ̀ nìyí: Ẹnikẹ́ni tí kì í ṣe òdodo kò wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹni tí kò nífẹ̀ẹ́ arákùnrin rẹ̀.+ 11 Torí ọ̀rọ̀ tí ẹ ti gbọ́ láti ìbẹ̀rẹ̀ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ ara wa;+ 12 kì í ṣe bíi Kéènì, tó jẹ́ ti ẹni burúkú náà, tó sì pa àbúrò rẹ̀.+ Kí nìdí tó fi pa á? Torí àwọn iṣẹ́ rẹ̀ burú,+ àmọ́ ti àbúrò rẹ̀ jẹ́ òdodo.+
-