-
Ẹ́kísódù 26:7-11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 “Kí o tún fi irun ewúrẹ́+ ṣe àwọn aṣọ àgọ́ láti fi bo àgọ́ ìjọsìn náà. Kí o ṣe aṣọ àgọ́ mọ́kànlá (11).+ 8 Kí gígùn aṣọ àgọ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ọgbọ̀n (30) ìgbọ̀nwọ́, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́rin. Kí ìwọ̀n gbogbo aṣọ àgọ́ mọ́kànlá (11) náà dọ́gba. 9 Kí o so márùn-ún nínú àwọn aṣọ àgọ́ náà pọ̀ mọ́ra, kí o so aṣọ àgọ́ mẹ́fà yòókù pọ̀ mọ́ra, kí o sì ṣẹ́ aṣọ àgọ́ kẹfà po níwájú àgọ́ náà. 10 Kí o lu àádọ́ta (50) ihò sí etí aṣọ àgọ́ tó wà ní ìkángun nínú ọ̀wọ́ náà, kí o tún lu àádọ́ta (50) ihò sí etí aṣọ àgọ́ tó wà ní ẹ̀gbẹ́ kejì, níbi tí wọ́n ti so pọ̀ mọ́ra. 11 Kí o fi bàbà ṣe àádọ́ta (50) ìkọ́, kí o sì fi àwọn ìkọ́ náà sínú àwọn ihò náà, kí o wá so àwọn aṣọ àgọ́ náà pọ̀ mọ́ra, yóò sì di odindi.
-