-
Ẹ́kísódù 28:22-25Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 “Kí o ṣe ẹ̀wọ̀n tó lọ́ pọ̀ sára aṣọ ìgbàyà náà, bí okùn tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe.+ 23 Kí o ṣe òrùka wúrà méjì sára aṣọ ìgbàyà náà, kí o sì fi òrùka méjèèjì sí igun méjèèjì aṣọ ìgbàyà náà. 24 Kí o ki okùn oníwúrà méjèèjì bọnú àwọn òrùka méjì tó wà ní igun aṣọ ìgbàyà náà. 25 Kí o wá ki etí okùn méjèèjì bọnú ìtẹ́lẹ̀ méjèèjì náà, kí o sì so wọ́n mọ́ àwọn aṣọ èjìká éfódì náà níwájú.
-