35 Ó sì fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa ṣe aṣọ ìdábùú.+ Ó kó iṣẹ́ sí i lára,+ iṣẹ́ náà jẹ́ àwòrán àwọn kérúbù.+
19 Torí náà, ẹ̀yin ará, nígbà tó jẹ́ pé a ní ìgboyà* láti wá sí ọ̀nà tó wọnú ibi mímọ́+ nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ Jésù, 20 èyí tó ṣí sílẹ̀* fún wa bí ọ̀nà tuntun, tó sì jẹ́ ọ̀nà ìyè tó la aṣọ ìdábùú kọjá,+ ìyẹn ẹran ara rẹ̀,