13 Torí tèmi+ ni gbogbo àkọ́bí. Lọ́jọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì,+ mo ya gbogbo àkọ́bí ní Ísírẹ́lì sí mímọ́ fún ara mi, látorí èèyàn dórí ẹranko.+ Wọ́n á di tèmi. Èmi ni Jèhófà.”
15 “Àkọ́bí gbogbo ohun alààyè,*+ tí wọ́n bá mú wá fún Jèhófà, ì báà jẹ́ èèyàn tàbí ẹranko, yóò di tìrẹ. Àmọ́, o gbọ́dọ̀ ra àkọ́bí èèyàn+ pa dà, kí o sì tún ra àkọ́bí àwọn ẹran tó jẹ́ aláìmọ́ pa dà.+
19 “Gbogbo àkọ́bí tó jẹ́ akọ nínú ọ̀wọ́ ẹran rẹ àti nínú agbo ẹran rẹ ni kí o yà sọ́tọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run rẹ.+ O ò gbọ́dọ̀ fi àkọ́bí nínú ọ̀wọ́ ẹran* rẹ ṣe iṣẹ́ kankan, o ò sì gbọ́dọ̀ rẹ́ irun àkọ́bí nínú agbo ẹran rẹ.
22 Bákan náà, nígbà tí àkókò tó láti wẹ̀ wọ́n mọ́ bó ṣe wà nínú Òfin Mósè,+ wọ́n gbé e wá sí Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n lè fún Jèhófà,*23 bí a ṣe kọ ọ́ sínú Òfin Jèhófà* pé: “Gbogbo àkọ́bí ọkùnrin* ni ká pè ní mímọ́ fún Jèhófà.”*+