ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Ẹ́kísódù 22:29
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 29 “O ò gbọ́dọ̀ lọ́ra láti mú nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ irè oko rẹ àti ohun tó kún àkúnwọ́sílẹ̀ nínú àwọn ibi ìfúntí* rẹ láti fi ṣe ọrẹ.+ Kí o fún mi ní àkọ́bí nínú àwọn ọmọkùnrin rẹ.+

  • Ẹ́kísódù 34:19, 20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 19 “Tèmi ni gbogbo ọmọkùnrin tó jẹ́ àkọ́bí,*+ pẹ̀lú gbogbo ẹran ọ̀sìn yín, yálà ó jẹ́ àkọ́bí akọ màlúù tàbí ti àgùntàn.+ 20 Kí ẹ fi àgùntàn ra àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ pa dà. Àmọ́ tí ẹ ò bá rà á pa dà, kí ẹ ṣẹ́ ọrùn rẹ̀. Kí ẹ ra gbogbo àkọ́bí nínú àwọn ọmọkùnrin yín pa dà.+ Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ wá síwájú mi lọ́wọ́ òfo.

  • Léfítíkù 27:26
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 26 “‘Àmọ́, kí ẹnì kankan má ya àkọ́bí ẹran sí mímọ́, torí ti Jèhófà ni àkọ́bí tí ẹran bá bí.+ Ì báà jẹ́ akọ màlúù tàbí àgùntàn, Jèhófà ló ni ín.+

  • Nọ́ńbà 3:13
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 13 Torí tèmi+ ni gbogbo àkọ́bí. Lọ́jọ́ tí mo pa gbogbo àkọ́bí nílẹ̀ Íjíbítì,+ mo ya gbogbo àkọ́bí ní Ísírẹ́lì sí mímọ́ fún ara mi, látorí èèyàn dórí ẹranko.+ Wọ́n á di tèmi. Èmi ni Jèhófà.”

  • Lúùkù 2:22, 23
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 22 Bákan náà, nígbà tí àkókò tó láti wẹ̀ wọ́n mọ́ bó ṣe wà nínú Òfin Mósè,+ wọ́n gbé e wá sí Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n lè fún Jèhófà,* 23 bí a ṣe kọ ọ́ sínú Òfin Jèhófà* pé: “Gbogbo àkọ́bí ọkùnrin* ni ká pè ní mímọ́ fún Jèhófà.”*+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́