-
Ẹ́kísódù 13:17, 18Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Nígbà tí Fáráò ní kí àwọn èèyàn náà máa lọ, Ọlọ́run ò darí wọn gba ọ̀nà ilẹ̀ àwọn Filísínì, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó wà nítòsí, torí Ọlọ́run sọ pé: “Àwọn èèyàn náà lè yí èrò pa dà tí wọ́n bá gbógun jà wọ́n, wọ́n á sì pa dà sí Íjíbítì.” 18 Torí náà, Ọlọ́run mú kí àwọn èèyàn náà lọ yí gba ọ̀nà aginjù tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun Pupa.+ Ṣe ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ nígbà tí wọ́n kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.
-