4 Màá jẹ́ kí ọkàn Fáráò le,+ ó máa lépa wọn, màá sì ṣe ara mi lógo nípasẹ̀ Fáráò àti gbogbo ọmọ ogun rẹ̀.+ Ó dájú pé àwọn ará Íjíbítì yóò mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.”+ Ohun tí wọ́n sì ṣe nìyẹn.
17 Nítorí Ìwé Mímọ́ sọ fún Fáráò pé: “Ìdí tí mo fi jẹ́ kí o máa wà nìṣó ni pé: kí n lè fi agbára mi hàn nípasẹ̀ rẹ àti pé kí a lè ròyìn orúkọ mi ní gbogbo ayé.”+18 Torí náà, ẹni tó bá wù ú ló ń ṣàánú, ẹni tó bá sì wù ú ló ń jẹ́ kó di olóríkunkun.+