-
Ìṣe 7:30-34Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
30 “Lẹ́yìn ogójì (40) ọdún, áńgẹ́lì kan fara hàn án ní aginjù Òkè Sínáì nínú ọwọ́ iná tó ń jó lára igi ẹlẹ́gùn-ún.+ 31 Nígbà tí Mósè rí i, ohun tó rí yà á lẹ́nu. Àmọ́ bí ó ṣe ń sún mọ́ ọn láti wádìí ohun tí ó jẹ́, ó gbọ́ ohùn Jèhófà* pé: 32 ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba ńlá rẹ, Ọlọ́run Ábúráhámù àti ti Ísákì àti ti Jékọ́bù.’+ Mósè bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ̀n, kò sì gbójúgbóyà láti sọ pé òun fẹ́ wádìí sí i. 33 Jèhófà* sọ fún un pé: ‘Bọ́ bàtà ẹsẹ̀ rẹ, torí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí. 34 Mo ti rí bí wọ́n ṣe ń fìyà jẹ àwọn èèyàn mi tó wà ní Íjíbítì, mo sì ti gbọ́ bí wọ́n ṣe ń kérora,+ mo ti sọ̀ kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n sílẹ̀. Ní báyìí, wá, màá rán ọ lọ sí Íjíbítì.’
-