Diutarónómì 6:16 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 16 “Ẹ ò gbọ́dọ̀ dán Jèhófà Ọlọ́run yín wò,+ bí ẹ ṣe dán an wò ní Másà.+ Sáàmù 95:8, 9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 Ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le bí ẹ ṣe ṣe ní Mẹ́ríbà,*+Bíi ti ọjọ́ Másà* ní aginjù,+ 9 Nígbà tí àwọn baba ńlá yín dán mi wò;+Wọ́n pè mí níjà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ mi.+ Hébérù 3:8, 9 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 8 ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le bó ṣe rí nígbà tí ẹ fa ìbínú tó le gan-an, bíi ti ọjọ́ tí ẹ fa àdánwò ní aginjù,+ 9 níbi tí àwọn baba ńlá yín ti dán mi wò, tí wọ́n sì dẹ mí wò, láìka àwọn iṣẹ́ mi tí wọ́n rí fún ogójì (40) ọdún sí.+
8 Ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le bí ẹ ṣe ṣe ní Mẹ́ríbà,*+Bíi ti ọjọ́ Másà* ní aginjù,+ 9 Nígbà tí àwọn baba ńlá yín dán mi wò;+Wọ́n pè mí níjà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti rí àwọn iṣẹ́ mi.+
8 ẹ má ṣe mú kí ọkàn yín le bó ṣe rí nígbà tí ẹ fa ìbínú tó le gan-an, bíi ti ọjọ́ tí ẹ fa àdánwò ní aginjù,+ 9 níbi tí àwọn baba ńlá yín ti dán mi wò, tí wọ́n sì dẹ mí wò, láìka àwọn iṣẹ́ mi tí wọ́n rí fún ogójì (40) ọdún sí.+