-
Léfítíkù 24:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Ó ṣẹlẹ̀ pé, láàárín àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, ọmọkùnrin kan wà tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì, tí bàbá rẹ̀ sì jẹ́ ará Íjíbítì.+ Òun àti ọkùnrin kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì wá ń bá ara wọn jà nínú ibùdó. 11 Ọmọkùnrin tí ìyá rẹ̀ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì náà wá bẹ̀rẹ̀ sí í tàbùkù sí Orúkọ náà,* ó sì ń sọ̀rọ̀ òdì sí i.*+ Torí náà, wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ Mósè.+ Ó ṣẹlẹ̀ pé, Ṣẹ́lómítì ni orúkọ ìyá rẹ̀, ọmọ Díbírì látinú ẹ̀yà Dánì.
-