10 Àmọ́, Jésù sọ fún un pé: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, Sátánì! Torí a ti kọ ọ́ pé: ‘Jèhófà* Ọlọ́run rẹ ni o gbọ́dọ̀ jọ́sìn,+ òun nìkan ṣoṣo sì ni o gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ fún.’”+
27 Ọkùnrin náà dáhùn pé: “‘Kí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ àti gbogbo okun rẹ àti gbogbo èrò rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà* Ọlọ́run rẹ,’+ kí o sì ‘nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì rẹ bí ara rẹ.’”+