16 “Àmọ́ tó bá sọ fún ọ pé, ‘Mi ò ní kúrò lọ́dọ̀ rẹ!’ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ ìwọ àti agbo ilé rẹ, tó sì jẹ́ pé inú rẹ̀ máa ń dùn nígbà tó wà lọ́dọ̀ rẹ,+ 17 kí o mú òòlu, kí o sì fi dá etí rẹ̀ lu mọ́ ara ilẹ̀kùn, ó sì máa di ẹrú rẹ títí láé. Bẹ́ẹ̀ náà ni kí o ṣe fún ẹrúbìnrin rẹ.