40 Ni Èlíjà bá sọ fún wọn pé: “Ẹ gbá àwọn wòlíì Báálì mú! Ẹ má ṣe jẹ́ kí ìkankan lára wọn sá lọ!” Ní kíá, wọ́n gbá wọn mú, Èlíjà wá mú wọn lọ sí odò* Kíṣónì,+ ó sì pa wọ́n níbẹ̀.+
20 Bẹ́ẹ̀ kọ́; àmọ́ ohun tí mò ń sọ ni pé àwọn nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè fi ń rúbọ, àwọn ẹ̀mí èṣù ni wọ́n fi ń rúbọ sí, kì í ṣe Ọlọ́run;+ mi ò sì fẹ́ kí ẹ di alájọpín pẹ̀lú àwọn ẹ̀mí èṣù.+