-
Diutarónómì 5:27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Ìwọ fúnra rẹ ni kí o sún mọ́ ibẹ̀, kí o lè gbọ́ gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run wa máa sọ, ìwọ lo sì máa sọ gbogbo ohun tí Jèhófà Ọlọ́run wa bá bá ọ sọ fún wa, a máa gbọ́, a sì máa ṣe é.’+
-
-
Jóṣúà 24:22Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
22 Torí náà, Jóṣúà sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lòdì sí ara yín pé, ẹ̀yin fúnra yín lẹ pinnu pé Jèhófà lẹ máa sìn.”+ Wọ́n fèsì pé: “Àwa ni ẹlẹ́rìí.”
-