-
Ẹ́kísódù 37:10-15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Ó wá fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe tábìlì.+ Gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, fífẹ̀ rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀.+ 11 Ó fi ògidì wúrà bò ó, ó sì ṣe ìgbátí wúrà sí i* yí ká. 12 Lẹ́yìn náà, ó ṣe etí tó fẹ̀ tó ìbú ọwọ́ kan* sí i yí ká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà sí etí náà yí ká.* 13 Ó tún fi wúrà rọ òrùka mẹ́rin fún un, ó sì fi wọ́n sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin níbi tí ẹsẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wà. 14 Àwọn òrùka náà sún mọ́ etí náà láti máa gba àwọn ọ̀pá tí wọ́n máa fi gbé tábìlì náà dúró. 15 Ó wá fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe àwọn ọ̀pá láti máa fi gbé tábìlì náà, ó sì fi wúrà bo àwọn ọ̀pá náà.
-