-
Ẹ́kísódù 36:20-23Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 Ó wá fi igi bọn-ọ̀n-ní+ ṣe àwọn férémù àgọ́ ìjọsìn náà, wọ́n sì wà ní òró.+ 21 Gígùn férémù kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá, fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀. 22 Férémù kọ̀ọ̀kan ní ìtẹ̀bọ̀ méjì* lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn. Bẹ́ẹ̀ ló ṣe ṣe gbogbo férémù àgọ́ ìjọsìn náà. 23 Ó ṣe àwọn férémù sí apá gúúsù àgọ́ ìjọsìn náà, ogún (20) férémù tó dojú kọ gúúsù.
-