-
Ẹ́kísódù 36:27-30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Ó ṣe férémù mẹ́fà sí ẹ̀yìn àgọ́ ìjọsìn náà lápá ìwọ̀ oòrùn.+ 28 Ó fi férémù méjì ṣe òpó sí igun méjèèjì àgọ́ ìjọsìn náà lápá ẹ̀yìn. 29 Àwọn òpó náà ní igi méjì láti ìsàlẹ̀ dé òkè, níbi òrùka àkọ́kọ́. Ohun tó ṣe sí òpó tó wà ní igun méjèèjì nìyẹn. 30 Gbogbo rẹ̀ wá jẹ́ férémù mẹ́jọ, pẹ̀lú ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn mẹ́rìndínlógún (16) tí wọ́n fi fàdákà ṣe, ìtẹ́lẹ̀ méjì tó ní ihò sì wà lábẹ́ férémù kọ̀ọ̀kan.
-