-
Ẹ́kísódù 36:35, 36Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
35 Ó sì fi fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa ṣe aṣọ ìdábùú.+ Ó kó iṣẹ́ sí i lára,+ iṣẹ́ náà jẹ́ àwòrán àwọn kérúbù.+ 36 Lẹ́yìn náà, ó fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe òpó mẹ́rin fún un, ó sì fi wúrà bò wọ́n, pẹ̀lú àwọn ìkọ́ tó fi wúrà ṣe, ó sì fi fàdákà rọ ìtẹ́lẹ̀ mẹ́rin tó ní ihò fún wọn.
-