-
Nọ́ńbà 4:14, 15Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
14 Kí wọ́n kó gbogbo ohun èlò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́ níbi pẹpẹ náà sórí rẹ̀: àwọn ìkóná, àwọn àmúga, àwọn ṣọ́bìrì àti àwọn abọ́, gbogbo ohun èlò pẹpẹ;+ kí wọ́n fi awọ séálì bò ó, kí wọ́n sì ki àwọn ọ̀pá+ tí wọ́n á fi gbé e bọ̀ ọ́.
15 “Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ gbọ́dọ̀ ti bo ibi mímọ́+ náà tán àti gbogbo ohun èlò ibi mímọ́ náà nígbà tí àwọn èèyàn* náà bá fẹ́ gbéra. Kí àwọn ọmọ Kóhátì wá wọlé wá gbé e,+ àmọ́ wọn ò gbọ́dọ̀ fara kan ibi mímọ́ kí wọ́n má bàa kú.+ Ojúṣe* àwọn ọmọ Kóhátì nínú àgọ́ ìpàdé nìyí.
-