-
Ẹ́kísódù 38:18, 19Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
18 Fọ́nrán òwú aláwọ̀ búlúù, òwú aláwọ̀ pọ́pù, òwú aláwọ̀ rírẹ̀dòdò àti aṣọ ọ̀gbọ̀ lílọ́ tó dáa tí wọ́n hun pọ̀ ni wọ́n fi ṣe aṣọ* tí wọ́n máa ta sí ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà. Gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún (20) ìgbọ̀nwọ́, gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, gíga rẹ̀ dọ́gba pẹ̀lú àwọn aṣọ ìdábùú tí wọ́n ta sí àgbàlá náà.+ 19 Bàbà ni wọ́n fi ṣe òpó wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin àti ìtẹ́lẹ̀ oníhò wọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. Fàdákà ni wọ́n fi ṣe àwọn ìkọ́ wọn àti àwọn ohun tó so wọ́n pọ̀,* wọ́n sì fi fàdákà bo orí àwọn òpó náà.
-