-
Ẹ́kísódù 28:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
28 “Kí o mú Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ látinú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí wọ́n lè di àlùfáà mi,+ Áárónì,+ pẹ̀lú Nádábù àti Ábíhù,+ Élíásárì àti Ítámárì,+ àwọn ọmọ Áárónì.+ 2 Kí o ṣe aṣọ mímọ́ fún Áárónì ẹ̀gbọ́n rẹ, kó lè ní ògo àti ẹwà.+ 3 Kí o bá gbogbo àwọn tó mọṣẹ́* sọ̀rọ̀, àwọn tí mo ti fi ẹ̀mí ọgbọ́n kún inú wọn,+ kí wọ́n lè ṣe aṣọ Áárónì láti sọ ọ́ di mímọ́, kó lè di àlùfáà mi.
-
-
Ẹ́kísódù 28:43Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
43 Kí Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ máa wọ̀ ọ́ nígbà tí wọ́n bá wá sínú àgọ́ ìpàdé tàbí nígbà tí wọ́n wá síbi pẹpẹ láti ṣiṣẹ́ nínú ibi mímọ́, kí wọ́n má bàa jẹ̀bi, kí wọ́n sì kú. Òun àti àwọn ọmọ* rẹ̀ gbọ́dọ̀ máa pa àṣẹ yìí mọ́ títí láé.
-