11 “Ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yóò fara mọ́ Jèhófà ní ọjọ́ náà,+ wọ́n á sì di èèyàn mi; èmi yóò sì máa gbé láàárín yín.” Ẹ ó sì mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló rán mi sí yín.
16 Kí ló pa òrìṣà pọ̀ mọ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run?+ Nítorí àwa jẹ́ tẹ́ńpìlì Ọlọ́run alààyè;+ bí Ọlọ́run ṣe sọ pé: “Èmi yóò máa gbé láàárín wọn,+ èmi yóò sì máa rìn láàárín wọn, èmi yóò jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì di èèyàn mi.”+