27 “Kí o fi igi bọn-ọ̀n-ní ṣe pẹpẹ;+ kí gígùn rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún, kí fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún. Kí ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin pẹpẹ náà dọ́gba, kí gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ta.+ 2 Kí o ṣe ìwo+ sí igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin; àwọn ìwo náà yóò wà lára pẹpẹ náà, kí o sì fi bàbà bo pẹpẹ náà.+