13 Àmọ́ Mósè sọ fún Ọlọ́run tòótọ́ pé: “Ká ní mo lọ sọ́dọ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí mo sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín rán mi sí yín,’ tí wọ́n sì bi mí pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’+ Kí ni kí n sọ fún wọn?”
6 Jèhófà ń kọjá níwájú rẹ̀, ó sì ń kéde pé: “Jèhófà, Jèhófà, Ọlọ́run aláàánú,+ tó ń gba tẹni rò,*+ tí kì í tètè bínú,+ tí ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀*+ àti òtítọ́*+ rẹ̀ sì pọ̀ gidigidi,