-
Ẹ́kísódù 19:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Kí o pa ààlà yí òkè náà ká fún àwọn èèyàn náà, kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ẹ má gun òkè náà, ẹ má sì fara kan ààlà rẹ̀. Ó dájú pé ẹnikẹ́ni tó bá fara kan òkè náà yóò kú. 13 Ẹnì kankan ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan ẹni náà, ṣe ni kí ẹ sọ ọ́ lókùúta tàbí kí ẹ gún un ní àgúnyọ.* Ẹ ò ní dá ẹ̀mí rẹ̀ sí, yálà ẹranko ni tàbí èèyàn.’+ Àmọ́ tí ìró ìwo àgbò bá ti dún,+ kí àwọn èèyàn náà wá sí òkè náà.”
-