-
Ẹ́kísódù 22:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 “Tí ẹnì kan bá fi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí akọ màlúù tàbí àgùntàn tàbí ẹran ọ̀sìn èyíkéyìí pa mọ́ sọ́dọ̀ ọmọnìkejì rẹ̀, tí ẹran náà wá kú tàbí tó di aláàbọ̀ ara tàbí tí ẹnì kan mú un lọ nígbà tí ẹnikẹ́ni ò rí i, 11 kí àwọn méjèèjì wá síwájú Jèhófà, kó lè búra pé òun ò fọwọ́ kan ẹrù ọmọnìkejì òun; kí ẹni tó ni ẹrù náà sì fara mọ́ ọn. Kí ẹnì kejì má san nǹkan kan dípò.+
-