-
Ẹ́kísódù 29:38-42Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
38 “Ohun tí ìwọ yóò fi rúbọ lórí pẹpẹ náà nìyí: ọmọ àgbò méjì tó jẹ́ ọlọ́dún kan lójoojúmọ́ títí lọ.+ 39 Kí o fi ọmọ àgbò kan rúbọ ní àárọ̀, kí o sì fi ọmọ àgbò kejì rúbọ ní ìrọ̀lẹ́.*+ 40 Kí o fi ọmọ àgbò àkọ́kọ́ rúbọ pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí: ìyẹ̀fun kíkúnná tó jẹ́ ìdá mẹ́wàá òṣùwọ̀n eéfà* tí o pò mọ́ ìlàrin òṣùwọ̀n hínì* òróró tí wọ́n fún àti ọrẹ ohun mímu tó jẹ́ wáìnì tó kún ìlàrin òṣùwọ̀n hínì. 41 Kí o fi ọmọ àgbò kejì rúbọ ní ìrọ̀lẹ́,* pẹ̀lú ọrẹ ọkà àti ọrẹ ohun mímu kan náà bíi ti àárọ̀. Kí o fi rú ẹbọ olóòórùn dídùn,* ọrẹ àfinásun sí Jèhófà. 42 Kí ẹ máa rú ẹbọ sísun yìí nígbà gbogbo jálẹ̀ àwọn ìran yín ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé níwájú Jèhófà, níbi tí màá ti pàdé yín láti bá yín sọ̀rọ̀.+
-
-
Nọ́ńbà 28:3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 “Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Ọrẹ àfinásun tí ẹ máa mú wá fún Jèhófà nìyí: kí ẹ máa mú akọ ọ̀dọ́ àgùntàn méjì tó jẹ́ ọlọ́dún kan tí ara wọn dá ṣáṣá wá lójoojúmọ́ láti fi rú ẹbọ sísun nígbà gbogbo.+
-