3 “‘Tí àlùfáà tí ẹ fòróró yàn+ bá dẹ́ṣẹ̀,+ tó sì mú kí àwọn èèyàn jẹ̀bi, kó mú akọ ọmọ màlúù kan tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá wá fún Jèhófà, kó fi rú ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ẹ̀ṣẹ̀ tó dá.+
12 gbogbo ohun tó kù lára akọ màlúù náà, kí ó kó o lọ sí ẹ̀yìn ibùdó níbi tó mọ́, tí wọ́n ń da eérú* sí, kó sì sun ún lórí igi nínú iná.+ Ibi tí wọ́n ń da eérú sí ni kó ti sun ún.