8 Kó máa tò ó síwájú Jèhófà nígbà gbogbo+ ní ọjọ́ Sábáàtì kọ̀ọ̀kan. Májẹ̀mú tí mo bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá ni, ó sì máa wà títí lọ. 9 Yóò di ti Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀,+ wọ́n á sì jẹ ẹ́ ní ibi mímọ́,+ torí ó jẹ́ ohun mímọ́ jù lọ fún un látinú àwọn ọrẹ àfinásun sí Jèhófà, ìlànà tó máa wà títí lọ ni.”