3“‘Tí ohun tó mú wá bá jẹ́ ẹbọ ìrẹ́pọ̀,*+ tó sì jẹ́ látinú ọ̀wọ́ ẹran ló ti fẹ́ mú un wá, yálà akọ tàbí abo, ẹran tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá ni kó mú wá fún Jèhófà.
21 “‘Tí ẹnì kan bá mú ẹran ẹbọ ìrẹ́pọ̀+ wá fún Jèhófà kó lè fi san ẹ̀jẹ́ tàbí kó lè fi ṣe ọrẹ àtinúwá, ẹran tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá ni kó mú wá látinú ọ̀wọ́ ẹran tàbí agbo ẹran, kó lè rí ìtẹ́wọ́gbà. Ẹran náà ò gbọ́dọ̀ ní àbùkù kankan.